Congratulations To An Oba Who Believes Every Child Counts

Congratulations To An Oba Who Believes Every Child Counts

Kabiyesi! E ku orire Odun tun tun
Oba Adedokun Omoniyi Abolarin
Agbgogbo moja
Agidigbi ebora omo
Agiri panpa Ebora owo
Agidimalaja ebora owo
Arosese ebora itura
Awolu ilu dero pese ,pese
Osipa omo , sipa owo
Afalafia se itele oro
Afanu sepin oju
Kebi pa Adedokun agungunla
Kongbe gbe Omoniyi aguntete
Omo Oke Ila ni ebi ko gbodo pa
Abinibi oke ila longbe o gbodo gbe
Amurewolu ti nko monamona
Asodedero ti nko monomona
Osupa ola ti ran lojo lerun
Orun aseyori ti ntan fun are ile ara oko
Omo onile ola to gba onile
Omo olodede iyun to gbalejo
Omo onile wura amuyagan fun oyinbo
O so feru ko ma rele
O fokun iwofa sile ko rode baba re
Toripe ba se bi eru la bimo
Omo ase biwofa la bi oloye
Omo ko siyato ninu omo ola atomo iwofa
Tori pe Ever child counts
Omo aje fun onile je
Omo amu fun alejo mu
A tun ori eni ti ko sunwon se
Oba iyi
Atorun muyiwaye Omoniyi
Iyi lotun , iyi losi
Orimadegun oba aroyinkeye
Awon kan mu ida,
Awon kan gbegba ata
Omo Abolarin gbe oyin
O ni aye ogun ko lohun wa
Irin ote ko ni mo rin
Oyin welu welu
Aye oyin ni fun gbogbo omo Okeila
Orangun Okeila oyin
Orangun oke ila owo
Itura logun arun
Oba Abolarin
Wa jayepe
Wa suwa suwa
Wa gborioye gbagbe ojo
Ajuwajuwa ileke
Awoso bi amutorunwa
Aringbende kile ma lu
Egan ko ni koyin in madun
Oba Adedokun Omoniyi Abolarin
Aroyinkeye
Orangun Oke Ila
Ogorun ni ti eru
Irinwo ni ti awon ijoye
Egberun odun ni toba
E seyi
E sere min
Kabiyesiiiiiiiiii poo
Gbogbo omo lomo

ALSO READ  Tradition! Whether Or Not To Re-marry Or Marry Them: Hottest Oloris Of The Late Octogenarian King Of Oyo Empire With Photos

Ambassador Wale Ojo – Lanre
Usi -Ekiti

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

You cannot copy content of this page