AWUJALE: 62 Years On The Throne

By The Editor

This day in history, April 2nd 1960, His Royal Majesty Oba Sikiru Kayode Adetona Ogbagba ll ascended the throne as the 55th Awujale of Ijebu Land.

Congratulations Kabiesi Ìjẹ̀bú ọmọ alárè,
Ọmọ arójò joyè,
Ọmọ alágemo merindinlogún,
Ọmọ aladìye ògògòmógà,
Ọmọ adìye bàlókùn,
Ara òrokùn,
Ara ò radìye,
Ọmọ ohun ṣéní,
òyòyò mayòmo ohun ṣéní,
olèpani, ọmọ dúdú ilé komobe ṣe níJósí,
Ọmọ moreye mamaroko, morokotan ẹyẹ mátìlo,
Ọmọ mo ní isunle mamalobe,
ọbẹ̀ tin be nílé kò mọ ilé baba tó bí wọn lọmọ,
Ọmọ onígbò ma’de,
Ọmọ onígbò mawo mawo,
Ọmọ onígbò ajoji magbodowo,
Àjòjì tobawo gboro yio di ebora ile baba tobi wan lomo.
Ìjẹ̀bú ọmọ èrè níwà,
Ọmọ olówó ìṣèmbáyé,
Òrìsà jẹ́ ń dàbí onílé yí,
kelebe Ìjẹ̀bú owó,
ìtò Ìjẹ̀bú owó ,
Dúdú Ìjẹ̀bú owó ,
Pupa Ìjẹ̀bú owó,
Kékeré Ìjẹ̀bú owó ,
Àgbà Ìjẹ̀bú owó.
Ìjẹ̀bú òde Ìjẹ̀bú ni,
Ìjẹ̀bú igbó Ìjẹ̀bú ni,
Ìjẹ̀bú isara Ìjẹ̀bú ni,
Ayépé Ìjẹ̀bú,
Ikorodu Ìjẹ̀bú Ìjẹ̀bú ní ṣe,
Ìjẹ̀bú Ọmọ oní Ilé ńlá ,
Ìjẹ̀bú Ọmọ aláso ńlá…Kaaaabiesi Ooo

 

Credit: Fb/Omo Lamurudu TV/Magazine

ALSO READ  Community Hospital Rehabilitation: Alawe Commends FG, Urges Site Engineers To Meet Specifications 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

You cannot copy content of this page